Interview with MarcDeMesel "The magnanimous" (Yoruba Language version)

4 60
Avatar for JoshuaDimeji
3 years ago

Ijomitoro pẹlu MarcDeMesel: Eni iyì (YORUBA VERSION)

 Loni, mo fẹ kọ́ lori onkan tó jẹ àkànṣe, bi mó ti ni ijomitoro pẹlu eni ti a mo fun funfun mi re si awujo owo ti a le fi oju ri sugbon ti a le fi owokan, BCH. Gbogbo eniyan ni awujo BCH lo mo MarcDeMesel, ti a si mo fun owo ti on fi sile. In mi dun lati le baa ni oro papo, mo si mo pe eyin naa ni pelu. E je ki a wa idahun si ibeere ki a lemo so nipa Marc.

Lati le juwe Marc le fun mi, mi o si ni le juwe bi o se je ninu oro mi. Marc ti je oloko-owo lati odun 2008, pelu ida ogoji (40%) ninu aka sile ti CARG. Marc je oloko-owo ninu owo ti a le fi owo kan ninu odun 2012. O ri nkan ti awọn èyán miran kò rí nínu àwọn owo náa. O jẹ ẹnikan ti o má n fun ni gẹgẹ bí gbogbo wà ṣe mọ wipe o jẹ gbajumọ ni itakun agbaye ayelujara YouTube. Lórí itakun agbaye re na, o ṣe àlàyé àwọn ìrírí re ati ìmọ idokowo ti o ní.

Nísìsiyìí, mí o fẹ jẹki eleyii súú yin, e jẹki a bẹrẹ ijomitoro pẹlu Marc


Ìbéèrè kínní: Gẹgẹ bí mó ṣe sọ, mi o ni le juwe yi daadaa, njẹ ẹ́ sọ fún wa nkan ti MarcDeMesel nse?

" Mo jẹ oludokowo, mo dokowo ninu owo ti a kólé fi owo kàn sí, eyen owo crypto ati ọjá míràn. Èmi maa nmu okowo mi fun odun púpọ bi a ti mo wi pe o ma npe ki okowo kan to gbera lati kekere, mo sí ma gbìyànjú láti táa".

Ìbéèrè Kejì: Nibo loti gbe dagba?

"Mo gbé dagba ni orile-ede Belgium, ni Europe, iwo gúúsù ti Dutch ti Belgium ti won pe ni Flandars. Won ni orisirisi ìlú kékeré to rewa bi Bruge, Ghents ati Antwerp pẹlú àwọn ilú ti aye àtijọ ti o rẹwa láti rìn nigba èèrùn ati gba afẹfẹ aye bi mímú lori awọn èbá ònà na".


Ìbéèrè kéta: Nisinsinyi, O je awokọṣe fun ẹgbẹrun ènìyàn, njẹ talo jẹ awokọṣe tirẹ abi ti o tóò si ọna?

"Mo ni ìmísí ati itosọ̀na lari aladani nla bi Bill Gates, Elon Musk, Roger Ver, ati awon olokowo nla bi Mare Faber, Roland Vandamme, Edward Thorp. Mo tun ni ìmísí lati pa ẹsẹ àwọn onímọ̀ ìjìnlè nla, onirorun ti o fun ni àti àwọn onímọ̀ nínú idokowo bi Nietzs Che, Ludwig Von Mises, Ayn Rand, Julian L. Simon ati Stefan Molyneux. Won po lopolopo mi mo se nife lati mo nípa wọn lórí ẹrọ ayélujára, titẹle aayan mi, wiwo àwòrán àti fiimu Agbelewo ni ojojumọ lori orisirisi nkan bi obinrin, ife ṣiṣe, oko ayọkẹlẹ. E le yẹ ori itakun àgbáyé mi (YouTube) nipa koko mi "Awọn akíkanjú mi"

https://www.youtube.com/playlist?list=PLJsRA97ztzdJxDXQ4LBU98TWCUjjbgDhU


Ìbéèrè kẹrin: Iwọ jẹ oludokowo púpọ àti wípé òkòwò sise nilo ero ọpọlọpọ riro, nje kini ipa opolo riro tire se jẹ?

"Ìbéèrè dáadáa niyen! mo ronu nipa àwọn idokowo mi, e mi sin máa nwo lati oriṣiriṣi igun, òun ti o le ma fẹ lo daada ati bi o se le rí bẹẹ. Mo gbìyànjú láti rí abala gidi ati buruku re, ewu ti o le romo ati ere ti o le muwa. Mo tun ma nwa papo pẹlu bi ọkan ati ará mi ma nṣe ati wipe nkan ti won sọ fún mi nípa èyán kan tabi idokowo".


Ìbéèrè kàrún: Iwọ bẹrẹ nínú ayé owo kripto nínú ọdún 2012 pẹlú Bitcoin. Nisinsinyi, o jẹ ọkan ninu awọn gbajumọ oluranlowo tabi Olùdásílẹ̀ ti Bitcoin cash (BCH). Njẹ kìlọ jẹ kí o yi ero re pada lati BTC si BCH?

"Tẹlẹ́ nisese bẹrẹ, laarin odun 2013, mo se akiyesi awọn iwa ti ko dara kan laarin awọn èyán ni Bitcoin. Wọn jẹ oniwa ti ko tona àti yẹ si àwọn owo kripto míràn bi Litecoin tàbí Peercoin, gẹgẹ bi emi na se ri ni isese bẹrẹ, riro wipe wo ko gbe ipa si ero ìsopọ̀ (nẹtiwọki) to ni agbára gidi bi bitcoin.

Sugbon, bi o tin sunmọ si opin ti ọdún 2013, emi ri pe fifi agbakagba o dara bi o tin mu nkan ti o dára nínú àwọn ènìyàn. Àwọn nkan wọnyi le ma t'ayọ, ṣugbọn awọn kàn ni ojo iwaju gegebi agbara ọjà awon owo kripto wọnyi ti tóbi gan, awọn ẹka míràn o si wáyé.

Bi ọdún ṣe n gori ọdún lora iwulo ti Bitcoin, gẹgẹ bí wọn ṣe pé jẹjẹ, o ri buruku de òpin orisirisi ero ti ko tọ ni wiwo ero asopọ ti Bitcoin gẹgẹ bíi èròjà tí kò wọpọ, nibi ti awon ti ofi ọwọ toga, leri ọna láti lọ sí iwájú.

Ni ibẹrẹ ọdun ti 2017, nigbati o hàn gbangba pé wọn koni f'iku iye idanudura ati ìyè ti apo na ati wipe títà rírà lobo máa wọn gidigidi ni ọjọ iwájú. Mo ni pupo mo si ta gbogbo BTC mi fún owo kripto míràn, gẹgẹ bí ọjọ se lọ bi oṣù kan ni owo ọjà ti BTC jawale lati marun lelogorin (80%) si marun le ogbọ́n (35%) péré, ni odun kan soso sí. Ni aarin ọdun 2017 ti Bitcoin Cash ge kuro lọdọ Bitcoin, inu mi dun gan mo síwá dokowo nla sibẹ lati isese bẹrẹ gẹgẹ bí a ti ni Bitcoin si ti wọn sì tóò dáadáa, ti gbogbo lilọ bibọ́ ti Onchain ri ni owo perete ti o sí yara, ati wipe orisirisi ọnà àti àpẹẹrẹ lati jẹ ki o tẹsiwaju lati fà gbogbo àpẹẹrẹ mìíràn ti o jẹmọ́ Bitcoin si dúró daadaa".


Ìbéèrè kẹfà: O ran iṣẹ iransẹ ti Flipstarter node pelu owó púpọ, o ran read.cash na lọwọ pẹlú owo púpọ. Awọn eniyan wa n béèrè iru anfaani wo ni o ma ri ninu awọn iranlọwọ naa. Kini awon eré tàbí anfaani ninu gbogbo iranlọwọ yi?

" Mo ni púpọ mo dé tun dokowo ninu Bitcoin ati Bitcoin cash nigbayen, kii se ni owó nikan sugbọn àkókò naa. Owó tí mo fí rán ẹgbẹ flipstarter jẹ kékeré ninu gbogbo timo ni, ti mi o ba de ṣe eleyii, iye orí ti Bitcoin cash le jawalẹ́ tabi dikun.

O jẹ idokowo olopolo pípé fúnmi lati ran read.cash bi àpẹẹrẹ pẹlu awọn owó púpọ, toriwipe wọn jẹ ọkan pataki to ni idaniloju lati maa lo Bitcoin cash bi owó tíó sile jékí eyan pupọ̀ máà lo ati láti fi BCH si ọwọ àwọn ènìyàn ti o tosí.

O rọrun lati kọ owó kripto lóni, sugbọn o soro lati ko eyi to maduro s'oto ati lati jẹki eyan lo kin se ogbon fifi ayelujara da nkan se nikan lóni lo sugbọn ọgbọn òkòwò na, ifowosowopo talẹnti ati ẹbun o sọwọn a sile ri ni read.cash ati egbe BCHN ti o nko nkan míràn ti o lo BitcoinABC, ati wipe egbé na ni akosilẹ̀ gidi, ifihan to dan geere, ati iṣẹ gidi, ibọwọ fun àwùjọ na awọn eniyan rẹ àti oludokowo, idi nìyẹn tí mo fi owo pupọ̀ ranwọ lọwọ".


Ìbéèrè keje: O jẹ bàbá gidi a sile ri ifẹ ti o ni sí àwọn ọmọ rẹ nínú àwòrán. Ayé nyi padà díèdíẹ̀ ati awọn nkan ayarabiasa n waye ju tẹlẹ lọ. Gẹgẹ bí bàbá, irufẹ awọn imọ tabi ogbon wo l'ofe ki awọn ọmọ rẹ ni ki wọn ba le tayọ ni ọjọ iwájú?

" Ẹsẹ pupo:) riro fún ara rẹ jẹ pataki, lilọ ìyè rẹ, ìrònú rẹ, ati be so wipe wọn je ọkan gboogi, mo sí nwa ìgboyà láti b'awọn sọrọ, tẹlẹ wọn, dokowo ninu won, o ṣòro, A je nkán to le ba awujo re wi àti pe ti èyán o ba ṣe, iku ni o nfa, idi nìyẹn ti a fi n tẹlẹ awujọ wa dáadáa, sibẹ ni idokowo ati sise fun ara eni, awujọ na ko tabi o pe latiri. O nilo lati wa ni iwájú na ti o ba fẹ ni owó àti pé ìrònú to daduro se pàtàkì.

Gẹgẹ bí ọmọdé ti èyán ma n nà latowo awon olukọ ati òbí ti o fe jẹ ki wọn se nkan to tona ati fún irú re ni iya to tọ fun aigbọran. Mo lero lati fun akoko to daa, ife àti isumo fun àwọn ọmọ mí, ju bi mo se ni lati awọn òbí témi. Funwon ni amojuto to dára nibi won le kọ nipa rírí nkan to daa, funwon ni anfani lati tẹle ọkàn wọn yàtọ sí ki wọn kọ nkan ti mo fẹràn abi nifẹ si, abikkíkọ wọn ni nkan ti ko dun mo wọn. Ọmọ ti a ba to daadaa, tí kò baje, ma di ọlọgbọn ju iwọ lọ ni ìmọ̀ púpọ kí wọ́n to de ọjọ ori mejidinlogun (18) ati lati tayọ ninu ọna tí wọn yan ti o simu owo wa, sugbọn o nilo iranlọwọ lati de be".


Ìbéèrè kẹjọ: Kilode ti o fí gbagbo ninu Bitcoin cash?

"Nítorípé Bitcoin cash ṣe dáadáa, to si ti tayọ ni ìsìn. Lòdì sí gbogbo odiwọn, Bitcoin tayo gẹgẹ bíi owo kripto to le da dúró, nínú asiko ti o jẹ iru ofin lati gbe iru e kalẹ gẹgẹ bí owo tirẹ àti fi egbekegbe pẹlu owó tí ìjọba. Awọn èyán to danwo tẹlẹ padanu e, awọn mìíràn si lo sí ẹwọn.

O tayọ nitoripe àkókò rẹ dara julọ. Ninu ọdún 2009 ni idojukọ ètò ajé lati ọgọrun odun àti pé àwọn adari ni orile-ede ni agbaye lo jere ninu owo ijoba, bi wọn ti n tẹ ni ojojumọ máa ko sínú àpò wọn, ni wọn ṣe odiwọn bóyá o ma tayọ. O tún tayọ nitori bi won ṣe se ati ipolowo re, ni nkan ti kosi eni to n dari e, ti o sí le fun awọn oloselu lati mu èyán to wa nìdí e, nipa fifi awọn ti o mọ nipa ayelujara si ẹwọn ati ọlọgbọn lai nìdí. Sugbọn wọn kólé bi lulẹ bi o ti je gbajugbaja, wọn si gbìyànjú láti ma wo lulo bi o se jẹ tẹlẹ wọn si je ki ẹka ìjọba bi ile-ifowopamo gbogbogbo lati ṣe ero nipa re, wọn si ri dajudaju pe ko ru òfin tàbí ki awọn èyáòn ma lo.

A mọ, wọn lò orisirisi ọnà mìíràn láti dẹ́kun idagbasoke rẹ. Ni ilu Amerika (USA), wọn pin pe ki nṣe owo ṣugbọn dukia, ti o sí jépé awọn ti o nlo ma san owo ori rẹ fún ìjọba lori gbogbo idanudura. Ọpọlọpọ orile-ede miiran o gbà wolo bi wọn o jẹ ki ile-ifowopamo wọn ṣe àmúlò rẹ, eyen awọn owó kripto, awọn ile-ifowopamo aladani si rii gẹgẹ bi nkan ti o segba won siti akan ti awọn eniyan to dokowo sinu rẹ.

Sugbọn, eyi ti o jẹ àṣeyọrí nlá ni pé Bitcoin n dagba s'oke o si yi idojukọ láti ọwọ́ to jẹ gbajugbaja eyan-si-eyan owó kripto ti o sí mú ominira ọrọ aje ni gbogbo agbaye koda si otosijulo, owó ti o jẹ fun itokoro lásán, níbí ti ibugbe Onchain je onkan ti oloro le ra ati bubu si abala Kejì níbí ti ipenija ati owo kripto yara wa.

Idi si leyi ti Bitcoin cash já kuro, láti má tele ọnà dúdú sugbọn tẹsiwaju nínú ọnà mímọ tí o wa, láti di gbajugbaja owó kripto aladani, to si gbaju nitori orukọ rẹ̀ tẹlẹ, ko wọn rara, o jara, o se gbẹkẹle gẹgẹ bí idanudura ati pe awọn ti o lo tun pọ. Ọpọlọpọ awọn owó kripto lo gbìyànjú láti ṣe ṣugbọn mo lero wipe Bitcoin cash ni anfani lati di eleyii".


Ìbéèrè kẹsán: Bitcoin cash je ki awọn orilẹ-ede miran gba gẹgẹ bi ọna sisan owo tàbí idanudura ati egbe BCH ti o nṣiṣẹ gidi nibe. Kíni imọran ìrù e fún àwọn èyán lorilede yí ki wọn le tayọ àti pé ri owó nínú ẹgbẹ yi?

"Láti ní àṣeyọrí nínú ayé owó kripto yi t'ọna lati ṣe, sugbọn o ṣòro. E wo kàn tọjú tabi fi owo rẹ pamọ́, wọn ni ṣeéṣe láti níye pupọ̀ lori. A mọ, ọpọlọpọ eniyan tàwọn ko to gbera lati sàn owó orisirisi nkan. Gbìyànjú láti ní owó kripto na bí ọjọ se nlọ bi funfun awọn eniyan ni nkan to níyì atí bi béèrè iye to se fi igbakagba. O le wa lori owó tí a kólé fi owo kàn pupọ̀ gẹgẹ bí alagbata àbí eni tó mọ nípa lílo ẹrọ ayélujára abi da òkòwò kan silẹ to nlo owó na abi kiko nipa rẹ lori read.cash. Se akiyesi nkan Jibiti pupọ̀, ko si kọ bi o sele dabobo owó re daada bi o ti je aye to niipon ti ayélujára ti iwa ole àti gibiti n ṣẹlẹ".


Ìbéèrè kẹwa: Mo le sọpe leyin opolopo isini yìí ati iranlọwọ at'okan si ọpọlọpọ iṣẹ ni ẹgbẹ BCH, ọpọlọpọ awọn eniyan loma wa siyin pelu oye tabi iranlọwọ lati sọ nkan. Kini imọran ti e ma fún wọn láti gba iranlọwọ lati ọdọ yin?

"Bọwọ fún àkókò mí, ge ni kukuru ko sì sọ oju abẹ niko. Fi han mi bi o ti njẹ ki Bitcoin cash o tayọ, inu mi a síi dùn láti ràn e lọwọ. Amò, opo ni o mu iye diẹ wa, o da ni oro ju fun nilo lo, mo wo bi o se nṣe, imujade ti tẹlẹ abi ti isisiyi. Àlọ ati ileri ni mi sábà ra. O lekan simi lori Telegram ni @marcdemesel ".


Ìbéèrè kọkànlá: Ni akotan, bawo ni o se lero pe BCH o da ni odun marun (5) si isiyin?

" Mo lero pe BCH o si máa jẹ ọkan ninu marun owó kripto na, àti wípé yo lo s'oke ni ọja. Ọpẹ pataki fún àwọn èyán ti o nri gẹgẹ bí Bitcoin tòótọ, ti ko wọn lórí, se gbẹkẹle, ati idanudura ti o ya gidigidi gẹgẹ bi Roger Ver to gbajumo sọ, ni iyato si BTC nibi ti awọn àmúyẹ ti yi pada ti a siri gíga gíga nínú owo sisan fun idanudura tàbí kí ìdàgbàsókè ma nkere síbi ọjọ se nlọ".


Ẹsẹ pupọ̀ MarcDeMesel


Modupé fun àkókò ti e fúnmi fun ijomitoro yi. O yami lenu si gbogbo idahun, ati wipe kika eyi jẹ kin mope kin ṣe ijomitoro lásán sugbọn o jẹ iriri odun mẹjọ (8) ti o ti salaye pẹlú wa. Èyán le toju odun mẹjọ re nipasẹ kíkà ìrírí sọrọ owó kripto ati "Bi O ti se". Fun awọn to nka, awọn ti nkọ ati ẹgbẹ́ Read.Cash, mo gbogbo sọpe eyi ni eniyan nla lati jẹ ki BCH dé ibi tí o wa nisin ati pe bí o se lerí gbogbo owo kripto ni ọjọ iwájú.

Mo lero pe bi emi, gbígbé eniyan le kogbon lati ki Marc púpọ, e sílè tẹle ero ayelujara re, gbami gbọ, nínú àwọn àwòrán yìí, o le kọ awọn ọgbọn to tayọ fún iwulo pupọ̀.


Youtube Channel: https://www.youtube.com/user/Marcdemesel

Twitter account : https://twitter.com/MarcDeMesel

Telegram: @marcdemesel


5
$ 4.00
$ 3.00 from @MarcDeMesel
$ 1.00 from @ralak
Sponsors of JoshuaDimeji
empty
empty
empty
Avatar for JoshuaDimeji
3 years ago

Comments

Man you tried on this one, I salute you for doing this work in my country native dialect.

$ 0.00
3 years ago

It really motivated me as i know i can still do more for the BCH adoption. It's better explained to natives. Thanks.

$ 0.00
3 years ago

Lols like you made this?

$ 0.00
3 years ago

Yeah i did it without Google translator because i believe it doesn't know my language as i do, it's my mother tongue of course! I translated everything down on my paper and did the typing and corrections with my phone

$ 0.00
3 years ago